Professor Peter Fatomilọla, the veteran Nollywood actor, bears his thoughts on the state of the nation.

Yorùbá nation is the way forward. Ojú á k’ára! We’ll be able to meet our leaders directly and talk with them.

Tí nwọ́n bá ní ẹnìkan ní Ijẹbu tàbí ará Ekiti kan l’ó n ṣ’olórí; tí aà bá fẹ́ nkan t’ó ń ṣe, àá lọ báa ní Ààfin Ààrẹ ni láti lọ fi ẹ̀dùn ọkàn-an wa hàn – nítorí èdè kan nã l’a jọ ń sọ! Ṣùgbọ́n ẹni t’óò gb’édèe ẹ̀, t’óò mọ̀n’wàa ẹ̀, t’óò mọ̀n’ran ẹ̀, t’óò mọ̀n’rìn-in ẹ̀, t’ó bá ń da’rí ẹ, t’ó ń f’ìyà jẹ ẹ́, t’óò dẹ̀ r’ẹ́ni gbà ẹ́ s’ílẹ̀; ẹrú aiyéraiyé ni ẹ́ ẹ̀! O dẹ̀ mã ṣ’ẹrú kú ni!

Àwọn kan ń sọ pé ṣé Ilẹ̀ ẹ Yoòbá ò níí kó sí wàhálàa ọ̀rọ̀ ẹni t’ó ma ṣ’olórí fún wa n’ígbàt’ã bá gba Òmìnira ọ̀hún nã tán? – Ẹ̀yin ẹ jẹ́ k’a lé Akátá lọ ná, k’a t’ó f’àbọ̀ bá’dìẹ̀!