Sauberfuss
Recent Posts
Connect with:
Thursday / December 1.
HomeOn’ílé ò fun’ra!

Main Home / Forums / Topics / On’ílé ò fun’ra!

Tagged: ,

 • This topic is empty.
Viewing 1 post (of 1 total)
 • Author
  Posts
 • #3889
  wp-admin
  Keymaster

  Ó ti wà n’ínú ìtàn Ìshẹ̀nbáiyé lát’ìgbà tí aiyé ti wà. Ìlú t’ó bá ti gbàgbé èdè ẹ̀; ẹ̀yà (race of people) tí nwọ́n kọ̀ lati kọ́ àwọn ọmọ wọn ní èdèe wọn, ti ṣe tàn láti parẹ́. Inú àwọn òbí t’ọ́n jẹ́ Yoòbá míìn á ma dùn nítorí ọmọ nwọn ò lè sọ ọ̀rọ̀ kan shosho lásán ní èdèe Yoòbá. Awọn ọmọ tí nwọ́n bí sí ilẹ̀ẹ Yooba ti nwọ́n dẹ̀ẹ̀ d’àgbà sí ilẹ̀ẹ Yoòbá!

  Ẹ wo àwọn Chinese, Indians àti Japanese; Òyìnbó kan ò fi ẹ̀sìn-in Christiani tàbí ti Islaamu kan tàn wọ́n jẹ! Èdèe wọn ni nwọ́n nsọ sí àwọn ọmọ wọn. Bí Òyìnbó bá lo ọgọ́rũn ọdún ní ìlú tí kìí ṣe ti wọn, èdèe wọn ni ọmọ wọ́n mã ma sọ!  Ẹ̀sìn ìbílẹ̀ẹ wọn ni nwọ́n dẹ̀ẹ̀ ń sìn. Àwọn Russians nã ò gb’ẹ́hìn. Ńbo n’ọ́n wà l’éni ní àwùjọ Ẹgbẹ́ àwọn ìlú t’ó ti lọ s’íwájú ti nwọ́n dẹ̀ẹ̀ ti g’òkè Àgbà, ẹ sọ fún mi?

  Ní ilẹ̀ẹ Yoòbá, kò sí abà, abúlé, ìletò, ìlú kékeré, ìlú ńlá kan, ti aà ti ní rí Onígbàgbọ́ tàbí Onímàle! Kódà, n’ínú ìdílé kan ṣoṣo, a lè rí ẹni t’ó jẹ́ Oníṣẹ̀ṣe, Onígbàgbọ́ tàbí Onímàle!

  Ñjẹ́, t’ọ́n bá ní kí orílẹ̀ èdèe Nigeria pínyà l’óríi ẹ̀yà oníkálukú (Yorùbá, Ibo, Hausa), ìshòro ò ní sí, àbí? Àkíìkà! Ṣùgbọ́n t’ọ́n bá ní k’a pínyà l’órí ẹ̀sìn ńkọ́? Tàbí ogun bẹ́ s’ílẹ̀ ní Nigeria laarin àwọn Onímàle àti Onígbàgbọ́? Kìí ṣe pé ilẹ̀ẹ Yorùbá mã parun tàbí parẹ́ ni? Ẹ̀sìn ti àwọn Òyìnbó tàbí àwọn Araabu bá ti ní k’a mã sìn l’ó dáa l’ójúu wa.

  L’ọ́wọ́ l’ọ́wọ́ báyï, ẹrù kan ń mì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ l’ókè; t’ó bá wá jábọ́, a bá ará-ilé, a bá ará-oko. Ẹ̀sìn ẹlẹ́sìn yï ló sọ wá d’èrò ẹ̀yìn l’áwùjọ àgbáyé!

  Pánsá ò sì fu’ra, pánsá já’áná, àjà ò fu’ra, àjá jìn! Ọ̀tá àwọn ènìà aláwọ̀ dúdú ni Òyìnbó àti Árãbù jẹ́ láti ìshẹ̀ndálẹ̀ aiyé.

  Ọ̀rọ́ kù s’ọ́wọ́ èmi àti ẹ̀yin.

  Translated into English for those who may have difficulty understanding this simple Yorùbá text (albeit being Yorùbás). Do click here.

Viewing 1 post (of 1 total)
 • You must be logged in to reply to this topic.